Elige una pista para reproducir
Mimọ l'Oluwa o (Mimọ)
Angẹli wọn mike o (Mimọ)
Awọn Ọrun wọn mike (Mimọ)
Ẹgbagbeje irawọ o (Mimọ)
Mimọ l'Oluwa (Mimọ)
Angẹli wọn mike o (Mimọ)
Awọn Ọrun wọn mike (Mimọ)
Ẹgbagbeje irawọ o (Mimọ)
Agbagba mẹrinlelogun (Mimọ)
L'origun mẹrẹrin aye o (Mimọ)
Ati oke, ati ilẹ (Mimọ)
Ṣeni wọn ke tan-tan o (Mimọ)
Tani o g'ori oke Oluwa? (Mimọ)
Tabi tani yoo duro ni'bẹ o? (Mimọ)
Ẹni to ni ọwọ mimọ (Mimọ)
Ati aya funfun o (Mimọ)
Mimọ l'Oluwa (Mimọ)
Mimọ o, Mimọ (Mimọ)
Mimọ o, Mimọ o, Mimọ (Mimọ)
Mimọ o, funfun nẹnẹ ni (Mimọ)
Kabiyesi Ẹlẹdumare, Ọba Mimọ (Mimọ)
Ọba nla, gbogbo aye ẹ tẹriba fun Ọba t'oda gbogbo adarihunhun
Ọba to ni eemi inu eniyan pata (Mimọ)
O ni kokoro aye l'ọwọ, adagodo emi gbogbo eniyan (Mimọ)
Olukangun-Ọrun, ajosi Edumare
Ibinigbi, awuwo bi atẹlẹ
Ọpa tirin kan'lẹ, o kan ọrun, minimini ojo ti n jẹ'ra, o d'eyan
Orun wawa, ki'gba o pada bọ si'po
Ọlọrun to s'ọṣupa d'alẹ, t'oru-t'oru
Ọba to n ṣe ohun gbogbo l'asiko, l'asiko (Mimọ)
Ọba to le fi ẹyin ẹniti, ta o le fi ẹyin Rẹ ti lai-lai
Are nla, Ọba t'ẹni kan o bi, to bi'mọ kari gbogbo aye poropodo
Olowo ori gbogbo aye pata-pata ni
Ọrọgọjigọ baba awọn ẹru (Mimọ)
(Mimọ) Oniwa funfun, Ọba adakẹ ṣe un, t'ẹnikan o le ṣe un si
Inu ogo gan-gan lo ti n fọ'hun (Mimọ)
Ologo to ju ogo lọ ni, Kabiọ-osi
Emi o jẹ fi Ọ ṣere, afi ẹni to ba fẹ gba query l'ọdọ Rẹ (Mimọ)
Mi o jẹ f'oju di Ọ, Ọba ti o ṣe wo loju-wo (Mimọ)
O ti ẹ le ti, ailenibajẹ ni Ọ
Baba nla ku, Baba mi, O le pin yẹnkẹ (Mimọ)
Gbogbo ẹni to ba mọ riri Oluwa
Ẹ tẹ riba, ẹ wa riri f'Ọba ti Itẹ Rẹ kii ṣi (Mimọ)
Ibẹrẹ ati opin, Ọlọrun ajanakun ti n mi igbo kiji, kiji, kiji (Mimọ)
Ta bubu, ta le bu tan, to n pọ si ni'gbogbo ọjọ
Ẹ jẹ ka ṣapa fun Ọba rere, ba-ba mọ riri
Emi inu awọn woli mimọ (Mimọ)
Atobitan, alainiye, ko kọja kika
Tẹrẹrẹ ko ja riri tọ, gigun lai lopin
Ailetunwo, adawunrọ, adawunsọ, adawunṣe (Mimọ)
Olu inu awọn ọrun, oke nla, arogumatidi
Arabaribiti, aribitirabata, ejikọta bi ko igi
Ojo g'oke bi ko yẹgẹrẹ, oke o le ṣa, oke o le yẹ
Ko s'ẹni to le mọ aditu Rẹ, Olodumare
Iwọ lo di, Iwọ lo le tu, Ọba nla, gbogbo agbaye lo n tẹriba fun Ọ, Baba Agba
Gbangban, gbangban, jọnran-jọnran, fẹn-fẹn, fẹn-fẹn, Iba o, iba
Mimọ l'Oluwa o (Mimọ)
Angẹli wọn mike o (Mimọ)
Awọn Ọrun wọn mike (Mimọ)
Ẹgbagbeje irawọ o (Mimọ)
Awọn ọrun sọrọ ogo Ọlọrun o
(Sọrọ, ogo Ọlọrun o sọrọ, ogo Ọlọrun o sọrọ)
Ati ofurufu, iṣẹ ọwọ Rẹ o (sọrọ, sọrọ iye)
Ogo Ọlọrun o
(Sọrọ, ogo Ọlọrun o sọrọ, ogo Ọlọrun o sọrọ, sọrọ, sọrọ iiye)
Ọjọ de, ọjọ n fọhun o (o n fọhun o)
Ati oru de oru fi mọrẹ (fi mọrẹ)
Ko si ohun kan tabi ede kan nibi ti a ko gbọ irọ wọn
(Irọ wọn la gbogbo aye ja, o-ay)
(Ati ọrọ wọn, ye o, ilẹ aye)
Ninu ogo Rẹ lo f'aṣẹ da oorun
(Pagọ, pagọ fun oorun o, pagọ, pagọ fun oorun, jade ti ẹbun rẹ wa)
O f'aṣẹ da oorun
(Pagọ, pagọ fun oorun o, pagọ, pagọ fun oorun jade ti ẹbun rẹ wa)
Oorun na yọ bi ọkunrin alagbara la ti sare ije
(La ti sare ije, la ti sare ije)
O yọ bi ọkunrin alagbara la ti sare ije
(La ti sare ije, la ti sare ije)
Ijade lọ rẹ ni la ti opin Ọrun wa (la ti opin Ọrun wa o)
Ayika rẹ o de ipilẹ
(De ipilẹ, de ipilẹ, de ipilẹ, de ipilẹ, ayika rẹ)
Ayika rẹ mo lo de ipilẹ
(De ipilẹ, de ipilẹ, de ipilẹ, de ipilẹ, ayika rẹ)
Ofin Oluwa pe o n yi ọkan pada
Ẹri Rẹ daniloju, o n sọ oke di ọlọkan
Ilana Oluwa tọ, o n mu ọkan yọ o
Aṣẹ Oluwa wa ni Mimọ, o n ṣe imọlẹ oju
Ẹru Oluwa mọ, wipe ni titi lai-lai
Idajọ o Oluwa ni otitọ, ododo ni gbogbo wọn
Ọlọrun ju wura to dara lọ
O si dun ju oyin lọ
Ko s'ẹni to le mọ aṣiṣe Rẹ (lai-lai, lai-lai)
Ko s'ẹni to le mọ aṣiṣe Rẹ (lai-lai, lai-lai)
Olodumare, ko s'ẹni to le mọ aṣiṣe Rẹ (lai-lai, lai-lai)
Ko s'ẹni to le mọ aṣiṣe Rẹ o (lai-lai, lai-lai)
Tori na, jẹ ki ọrọ ẹnu mi (ay-ay)
Iṣaro ọkan mi (iṣaro ọkan mi)
Ko ṣe itẹwọgba ni oju Rẹ o, Oluwa
Jẹ ki ọrọ ẹnu mi, iṣaro ọkan mi (ay-ay)
Ko ṣe itẹwọgba ni oju Rẹ o, Oluwa (let the words of my mouth)
Let the words of my mouth (ay-ay)
Meditation of my heart (meditation of my heart)
Be accepted in Thy sight, oh Lord (in Thy sight)
Let the words of my mouth (ay)
Meditation of my heart
Be accepted in Thy sight, oh Lord
Jẹ ki ọrọ ẹnu mi, iṣaro ọkan mi (iṣaro ọkan mi)
Ko ṣe itẹwọgba (Oluwa) ni oju Rẹ o, Oluwa (ma tarọ ẹṣẹ mi)
Jẹ ki ọrọ ẹnu mi, iṣaro ọkan mi (ay-ay)
Ko ṣe itẹwọgba ni oju Rẹ, Oluwa
Ẹru Rẹ ba mi o-o-o (ẹru Rẹ ba mi)
Ọba to f'ogun Pharaoh ṣofo sinu okun pupa
Ti keke, ti keke (ẹru Rẹ ba mi)
Ay (ipa to ka gbogbo aye, 'la niun ọlanla)
Ọba o (Ọba to p'ọkọ de yanrin leti okun, ẹru Rẹ ba mi o, Baba)
Ẹru Rẹ ba mi o-o-o (ẹru Rẹ ba mi)
Nebukadinasari d'ẹranko f'ọdun meje, iṣẹ ọwọ Rẹ ni, Baba
(Ẹru Rẹ ba mi, ipa to ka gbogbo aye, 'la niun ọlanla)
Ọba nla (Ọba to p'ọkọ de yanrin leti okun, ẹru Rẹ ba mi o, Baba)
Ka-kabiọsi o, oṣuba Rẹ maa re
Kabiyesi Rẹ, Iyin Rẹ re
Ipa to ka gbogbo aye, 'la niun ọla
Ọba to sọrọ ti ina yọ, ẹru Rẹ ba mi o, Baba
Ẹru Rẹ ba mi o-o-o (ẹru Rẹ ba mi)
Ẹni kẹrin niun ina ile ru, ẹru Rẹ ba mi o, Baba
(Ẹru Rẹ ba mi, ipa to ka gbogbo aye, 'la niun ọlanla)
Ọba o (Ọba to p'ọkọ de yanrin leti okun, ẹru Rẹ ba mi o, Baba)
Ẹru Rẹ n ba mi o (ẹru Rẹ ba mi)
Ayeraye, Ọlọrun iyanu, ẹru Rẹ ba mi o, Baba
(Ẹru Rẹ ba mi) ay-ay
(Ipa to ka gbogbo aye, 'la niun ọlanla)
(Ọba to p'ọkọ de yanrin leti okun, ẹru Rẹ ba mi o, Baba)
Ẹru Rẹ n ba mi o-o (ẹru Rẹ ba mi)
Okele-bamba ti o ṣe, gbe mi f'oṣo o, oun at'ajẹ o, Baba rere
(Ẹru Rẹ ba mi, ipa to ka gbogbo aye, 'la niun ọlanla)
Nla niun ọnla (Ọba to p'ọkọ de yanrin leti okun, ẹru Rẹ ba mi o, Baba)
Ẹru Rẹ ba mi o, Ba (ẹru Rẹ ba mi)
Ọlọrun Ajanaku ti n mi'gbo kiji-kiji, Baba mi (ẹru Rẹ ba mi)
O ṣe (ipa to ka gbogbo aye, 'la...)